Arìn ìrìn àjò mi ò m'aìdélé Mo wọ̀lú, mo yà bàrà délé onínnkan Ló bá ní n fobọ́, kí n tó wẹwọ, kí n tó jẹ iyán Wọ́n ní n bẹṣu, kí 'n tó yọfe, kí n tó m'ògùrọ̀ Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn Ó ló ju t'òhun lọ, kò ma rán Ta ni baba tó bí mi l'ọmọ? Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s'awọn Àmọ́ o ràn (O ràn) O ràn (O ràn) O ràn, òkìkí mí ràn O ràn (O ràn) O ràn (O ràn) O ràn, òkìkí mí ràn Mo ronú títí, mo gbọ́rọ̀ tì, n ò lè paátì Ẹni abíire ni mí, n ò lè fòdodo ṣawátì Nṣe ni mo bò s'ọ̀nà, mo wọ sálubàtà, mo gẹ fìlà Nṣe ni mo bò s'ọ̀nà, n ò rìn fìà-fìà, n ò ṣẹ fàlà-fàlà Balógun ló fẹ́ ṣoṣó dẹrú kó má ràn Ó ló ju t'òun lọ, kò ma rán Ta ni baba tó bí mi l'ọmọ? Ibo mo ti ṣè wá? Wà n ruga s'awọn Àmọ́ o ràn (O ràn) O ràn (O ràn) O ràn, òkìkí mí ràn O ràn (O ràn) O ràn (O ràn) O ràn, òkìkí mí ràn Balógun ló fẹ́ p'òkòkí ẹlòmíràn Ó ló ju t'òun lọ, kò ma rán Pe ta ni baba tó bí mi l'ọmọ? Ọ̀gbẹ̀rì lawo níwájú òrìṣà kò mọ Àmọ́ o ràn O ràn, o ràn N ò fẹ́ òkìkí òmíràn O ràn O ràn O ràn, òkìkí mí ràn